Manuel Quintana
Manuel Quintana jẹ́ Ààrẹ orílẹ̀-èdè Argentina tẹ́lẹ̀.
Manuel Quintana jẹ́ adarí Ààrẹ orílẹ̀-èdè Argentina President of Argentina láàárín ọdún 1904 sí ọdún 1906. Wọ́n bí i ní ọdún 1835 ní Buenos Aires, tí ó sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ òfin Law . Quintana jẹ́ ènìyàn kan tí ó nífẹ̀ẹ́ sí ètò òṣèlú Politics fún ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú kí ó tó di Ààrẹ orílẹ̀ èdè Argentina Argentina. Nígbà tó wà nínú ọ̀rọ̀ òṣèlú, ó ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí olóṣèlú àgbà, tó sì ní ipa takuntakun lórí ètò òfin àti ọ̀rọ̀ òṣèlú, pẹ̀lú àjọṣepọ̀ àwọn ọ̀gá gíga mìíràn.
Nígbà tí Quintana jẹ́ Ààrẹ orílẹ̀-èdè Argentina, ìlú Argentina rí onírúurú ìdàgbàsókè nípa ètò ọrọ̀ ajé Economy àti nípa ìdàgbàsókè àwọn ilé iṣẹ́, ṣùgbọ́n kọ́kọ́rọ́ kan ba eyín ajá jẹ́, ní ìgbà ìṣẹ́jọba rẹ̀ onírúurú ìjà òṣèlú ni ó ń bẹ́ sílẹ̀. Ó dojú kọ́ àwọn ìṣòro kan láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá ìṣèjọba rẹ̀ tí ó sì mú ìyípadà tó lóòrìn bá ààbò ìjọba rẹ̀. Ní ọdún 1905, àwọn ènìyàn kan gbìmọ̀ pọ̀ láti kọlu ìjọba rẹ̀ wọ́n sì ṣe ìkọ̀lù tó yàtọ̀ láti yọ ọ́ kúrò lórí àlééfà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kó Quintana yọ ó sì ṣe àṣeyọrí.
Pẹ̀lú gbogbo àwọn ìdojúkọ yìí, ìgbésí ayé Quintana kúkú jẹ́ àkókò tó kún fún ìjà àti ìṣòro tí wọ́n sì nípa lórí ètò ìlera rẹ̀, tó sì padà yọrí fífi ipò sílẹ̀ lojìji nípa kí kọ̀wé fi ipò àárẹ́ sílẹ̀ látàrí àìsàn èyí tí ó mu. Quintana kí ayé yìí pé ó di ìgbà ní ọdún 1906 nígbà tí ó wà nípò, látàrí ètò ìlera èyí tí ó kùnà.